Afọlaṣadé mi Noimot Fọláṣadé mi tì ẹ yàtọ̀ o Ọmọ oní Ṣadé mi Noimot o Fọláṣadé mi Noimotu Aya Eleganza mi Àkànní adé Noimot, Fọláṣadé baby sweetie Noimot Noimot Fọláṣadé (Noimot Fọláṣadé) Aya Àkànní Rasa (Aya Àkànjí Rasaki mi) Áńgẹ́lì Ọ (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya) Fọláṣadé tì ẹ́ (Fọláṣadé tì ẹ yàtọ̀) Bí wọ́n bá gbẹ́ kòtò bí wọ́n bá gbẹ́ní le lórí o Bí wọ́n bá ní o wá sùn’le Noimot Ṣadé Iná bá dálẹ̀ di ẹyẹ gúnnugún Ẹyẹ míì ni wọ́n fi ń sun Wasiu mo ti sọ Afọláṣadé Noimotu o Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé Kiníkan kò mà ní ṣe ẹ́ o (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Aya onílé ajé Àkànní Rasaki baàmi (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Ọmọ ti Nimotallahi mi (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Owó mother Ọlámidé o mother Ṣùbòmí o (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Noimot mother t’Oyinlọlá o mother Wahabi mi (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Ẹ̀mí gangan Àkànní o tí ń jẹ́ Rasaki Baàmi (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Kiní kan ò mà ní ṣe ẹ́ o, Noimot bo ṣe ń tọ́jú bàbá mi (Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Noimotu Fọláṣadé) Ah! Jayé pẹ́ jayé pẹ́ Àyìndé o (Òwìrì jayé pẹ́) Baàmi Àkànní o ma jayé ju báyìí lọ (O ti ń jayé pẹ́) Àkànní, ta ló ń ṣagídí ṣagídí? Agídí ò rán o Ẹ rọra dìtẹ̀ dìtẹ̀ dìtẹ̀ (K’ọ́tẹ̀ má tẹ̀ wọ̀n o) Alhaja Muinat Ọkọ́ya ní n kí ẹ Fọláṣadé Goldrush ní n kí ẹ Noimotu mi Afọláṣadé Noimotu o Wọ́n ó le wọn ò le bá o o (Láyé, wọ́n ó le wọn ò le bá) O lọmọ ńlá o ti ṣẹ́ corner (Wọ́n ó le wọn ò le bá) Afọláṣadé o Noimotu Afọláṣadé o Noimotu mi Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Àkànní Rasaki (Afọláṣadé o Noimotu mi) Kiní kan ò mà ní ṣe ẹ́ o ṣá ma rìn máa yanfanda (Afọláṣadé o Noimot o) Aya baàmi Àkànní o tí ń jẹ́ Rasaki (Afọláṣadé o Noimot o) Mother Ya Wahabi mi mother Oyinlọlá Mother Ṣùbòmí mother t’Ọlámidé o máa gbésẹ̀ ni kọ̀ọ̀kan (Afọláṣadé o Noimotu o) Nkiru baby ní n kí ẹ ṣá máa rìn máa yanfanda (Afọláṣadé o Noimot o) Mosúnmọ́lá baby ní n kí ẹ Noimotu mi (Afọláṣadé o Noimot o) Nkiru Baby ní n kí ẹ Noimo (Afọláṣadé o Noimot o) Gbogbo wa là ń kí ẹ ṣá ma rìn Fọláṣadé (Afọláṣadé o Noimot o) Áńgẹ́lì Ọkọ́ya Àkànní Rasaki baàmi (Afọláṣadé o Noimot o) Engineer Saratul ní n kí ẹ ma rìn ma yanfanda (Afọláṣadé o Noimot o) Adija oritóké ọ̀rẹ́ mi Adija, ó. Mà ní n kí ẹ Alhaji Wasiu Àyìndé (Afọláṣadé o Noimot o) Ọmọ́táyọ̀ baby aya Bashir mi ayaba Kóredé òun náà ní n kí ẹ ṣá ma rìn ma yanfanda (Afọláṣadé o Noimot o) Jazakallahu mi Airatu Ṣé ò ń gbọ́? (Afọláṣadé o Noimot o) Alhaja Muina, Muina Shagaya o ní n kí ẹ Fọláṣadé (Afọláṣadé o Noimot o) Gbogbo wa là ń ṣe àdúrà fún ẹ O kú Ìtọ́jú bàbá mi Fọláṣadé ò ń rí gbà lò kò dẹ̀ lè kan fún ẹ lọ́la Muhammad mi (Afọláṣadé o Noimot o) Ọ̀rẹ́ mi Adija, ó mà ní n kí ẹ Adijatu Kubure (Afọláṣadé o Noimot o) Yétúndé baby òun náà mà ní n kí ẹ aya Dodo Balógun, ṣá ma rìn máa yanfanda (Afọláṣadé o Noimot o) Ṣadé w’èrò (wèrò lẹ́yìn ẹ o) (Ò ń jọlá ìwà ẹ) Noimotu w’èrò (wèrò lẹ́yìn ẹ o) (Ò ń jọlá ìwà ẹ) (Ìwà ló yẹ ká lo ọ̀rẹ́dọlá) (Ìwà ló yẹ ká wò níbi kíbi t’a bá wà láwùjọ) Bẹ́ẹ̀ ló rí o eh! (bẹ́ẹ̀ ló rí o eh) Óyá ẹ jẹ́ ká kàá síwájú Noimotu o (Noimotu) Noimotu o (Noimotu) Noimo Ọkọ́ya (Noimotu) Noimo Ọkọ́ya (Noimotu o) Nosa ní n kí ẹ (Noimotu) Èmi náà ń kí ẹ (Noimotu) Nkiru ní n kí ẹ (Noimotu) Sister mo ní n kí ẹ (Noimotu o) Èmi náà ń kí ẹ (Noimotu) Nkiru ní n kí ẹ (Noimotu) Noimo jayé orí ẹ (Afọláṣadé) Noimo jayé orí ẹ (Afọláṣadé) Ìyà kan ò mà ní ẹ ẹ́ jẹ (Afọláṣadé) Noimo, Nkiru ní n kí ẹ (Afọláṣadé) Nkiru ní n kí ẹ (Afọláṣadé) Mo ní n kí ẹ (Afọláṣadé) Ìyá kan ò mà ní ẹ ẹ́ jẹ (Afọláṣadé) Sister Focus ní n kí ẹ (Afọláṣadé) Òyìnbó Ọkọ́ya (Noimotu mi) Àwọn Ọ̀rẹ́dọlá ní n kí ẹ (Noimotu mi) Olori Elegushi ní n kí ẹ (Noimotu mi) Olorì olówòrò ní n kí ẹ (Noimotu mi) Olorì Ọba Ẹ̀pẹ́ ó ní kí n kí ẹ (Noimotu mi) Olorì Alárá ní n kí ẹ (Noimotu mi) Saratul ní n kí ẹ (Noimotu mi) Saratul ní n kí ẹ (Noimotu mi) Ọmọ́táyọ̀ ní n kí ẹ (Noimotu mi) Aya Bashir ní n kí ẹ (Noimotu mi) Jókòó ní n kí ẹ o (Noimotu mi) Oritókẹ́ Adija ní n kí ẹ (Noimotu mi) O mà kú ìnáwó (Adija Kuburatu o) O kú ìnáwó mi (Adija Kuburatu o) O mà kú ìnáwó (Adija Kuburatu o) O kú ìnáwó mi (Adija Kuburatu o) O mà kú ìnáwó (Adija Kuburatu o) O mà kú ìnáwó mi (Adija Kuburatu o) Ó ní n kí Fọláṣadé Noimo mi o Kí n kí Ṣadé Noimo mi o Aya baàmi Àkànní Adé, Àkànní Eleganza o Ẹ̀yin ẹ lu àlùjó gbésẹ̀ nítorí Fọláṣadé Àlùjó gbésẹ̀ (nítorí Fọláṣadé) Ọ̀rọ̀ yìí d’àlùjó gbẹ́sẹ̀ nítorí Fọláṣadé Gbẹ́sẹ̀, gbẹ́sẹ̀, gbẹ́sẹ̀, gbẹ́sẹ̀ Ó d’àlùjó gbésẹ̀ (nítorí Fọláṣadé)